1. Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí:
2. Gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ó rí:“Ọlọrun ní,‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹòun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’
3. Ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé,‘Ẹ la ọ̀nà tí Oluwa yóo gbà,ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ”
4. Báyìí ni Johanu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrìbọmi ninu aṣálẹ̀, tí ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n.