4. Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni.
5. Ó lọ kọ orúkọ sílẹ̀ pẹlu Maria iyawo àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó lóyún, tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ.
6. Ó wá yá nígbà tí wọ́n wà ní Bẹtilẹhẹmu, àkókò tó fún Maria láti bímọ.
7. Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò.
8. Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru.