Lefitiku 9:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli;

2. ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.

3. Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.

Lefitiku 9