Lefitiku 18:9-16 BIBELI MIMỌ (BM)

9. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin rẹ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lobinrin, tabi ọmọ baba rẹ lobinrin, kì báà jẹ́ pé ilé ni wọ́n bí i sí tabi ìdálẹ̀.

10. O kò gbọdọ̀ bá ọmọ ọmọ rẹ lobinrin lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ obinrin tabi ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin, nítorí ohun ìtìjú ni ó jẹ́ fún ọ, nítorí pé, ìhòòhò wọn jẹ́ ìhòòhò rẹ.

11. O kò gbọdọ̀ bá ọmọ tí aya baba rẹ bá bí fún baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, arabinrin rẹ ni.

12. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí baba rẹ ni ó jẹ́.

13. O kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí ìyá rẹ ni ó jẹ́.

14. O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún ọ.

15. O kò gbọdọ̀ bá aya ọmọ rẹ lòpọ̀, nítorí pé, aya ọmọ rẹ ni.

16. O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ohun ìtìjú ni, ìhòòhò arakunrin rẹ ni.

Lefitiku 18