Lefitiku 14:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ.

11. Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

12. Lẹ́yìn náà, yóo mú ọ̀kan ninu àwọn ọ̀dọ́ àgbò náà, yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

13. Alufaa náà yóo pa àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ẹbọ sísun ninu ibi mímọ́, nítorí pé ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi jẹ́ ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ohun mímọ́ patapata ni.

Lefitiku 14