14. Ṣugbọn kí ẹ jẹ igẹ̀ tí ẹ bá fi rú ẹbọ fífì ati itan ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ní ibi mímọ́, ìwọ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn ọmọbinrin rẹ, nítorí pé ìpín tìrẹ ni, ati ti àwọn ọmọkunrin rẹ, ninu ẹbọ alaafia, tí àwọn eniyan Israẹli rú.
15. Nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀rá ẹran wá fún ẹbọ sísun, tí wọ́n mú itan ẹran tí wọ́n fi rúbọ, ati igẹ̀ àyà rẹ̀ fún ẹbọ fífì níwájú OLUWA, yóo máa jẹ́ tìrẹ, ati ti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín yín títí ayé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”
16. Mose fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí nípa ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sì rí i pé wọ́n ti dáná sun ún. Inú bí i sí Eleasari ati Itamari, àwọn ọmọ Aaroni tí wọ́n ṣẹ́kù, ó ní,