11. Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.
12. Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.
13. Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;
14. àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu,
15. Sebadaya, Aradi, ati Ederi,
16. Mikaeli, Iṣipa ati Joha.