6. Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu,
7. Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu.
8. Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi,
9. Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani.
10. Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).
11. Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu;
12. Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu.
13. Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya,