17. Àwọn ọmọ Jehoiakini, ọba tí a mú lẹ́rú lọ sí Babiloni nìwọ̀nyí: Ṣealitieli,
18. Malikiramu, Pedaaya, ati Ṣenasari, Jekamaya, Hoṣama ati Nedabaya.
19. Pedaaya bí ọmọ meji: Serubabeli, ati Ṣimei. Serubabeli bí ọmọ meji: Meṣulamu ati Hananaya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣelomiti.
20. Serubabeli tún bí ọmọ marun-un mìíràn: Haṣuba, Oheli, ati Berekaya; Hasadaya ati Juṣabi Hesedi.