1. Dafidi ati àwọn olórí ogun ya àwọn kan sọ́tọ̀ ninu àwọn ọmọ Asafu, Hemani ati ti Jedutuni láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fi dùùrù, ati hapu ati aro kọrin. Àkọsílẹ̀ àwọn tí a yàn ati iṣẹ́ wọn nìyí:
2. Lára àwọn ọmọ Asafu wọ́n yan Sakuri, Josẹfu, Netanaya, ati Asarela; wọ́n wà lábẹ́ àkóso Asafu, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ àkóso ọba.