Kronika Kinni 22:10-12 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ó ní ọmọ náà ni yóo kọ́ ilé fún òun. Yóo jẹ́ ọmọ òun, òun náà yóo sì jẹ́ baba rẹ̀. Ó ní òun óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Israẹli títí lae.

11. “Nisinsinyii, ìwọ ọmọ mi, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ, kí o lè kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun rẹ fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.

12. Kí OLUWA fún ọ ní ọgbọ́n ati làákàyè kí o lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́ nígbà tí ó bá fi ọ́ jọba lórí Israẹli.

Kronika Kinni 22