1. Dafidi kọ́ ọpọlọpọ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó tọ́jú ibìkan fún Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ó sì pa àgọ́ lé e lórí.
2. Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”