13. Láìpẹ́, àwọn ará Filistia tún wá gbógun ti àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, wọ́n sì kó wọn lẹ́rú.
14. Dafidi bá tún lọ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun. Ọlọrun sì dá a lóhùn pé, “Má ṣe bá wọn jà níhìn-ín, ṣugbọn yípo lọ sẹ́yìn wọn kí o kọlù wọ́n ní òdìkejì àwọn igi balisamu.
15. Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.”
16. Dafidi ṣe ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún un, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Gibeoni títí dé Gasa.