3. Kí á sì lọ sí ibi tí Àpótí Majẹmu Ọlọrun, tí a ti patì láti ayé Saulu wà, kí á gbé e pada wá sọ́dọ̀ wa.”
4. Gbogbo ìjọ eniyan sì gbà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó dára lójú wọn.
5. Nítorí náà Dafidi kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti Ṣihori ní Ijipti títí dé ẹnubodè Hamati láti lọ gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun láti Kiriati Jearimu lọ sí Jerusalẹmu.
6. Dafidi ati gbogbo ọmọ Israẹli lọ sí ìlú Baala, tí à ń pè ní Kiriati Jearimu, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu tí à ń fi orúkọ OLUWA pè, OLUWA tí ó jókòó, tí ó fi àwọn Kerubu ṣe ìtẹ́.
7. Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà jáde láti ilé Abinadabu, wọ́n gbé e lé orí kẹ̀kẹ́ titun. Usa ati Ahio sì ń wa kẹ̀kẹ́ náà.
8. Dafidi ati àwọn eniyan ń fi tagbára-tagbára jó níwájú Ọlọrun, pẹlu orin ati àwọn ohun èlò orin: dùùrù, hapu, ìlù, Kimbali ati fèrè.
9. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Kidoni, àwọn mààlúù tí wọn ń fa kẹ̀kẹ́ náà kọsẹ̀, Usa bá di Àpótí Majẹmu náà mú kí ó má baà ṣubú.
10. Ṣugbọn inú bí Ọlọrun sí Usa, ó sì lù ú pa, nítorí pé ó fi ọwọ́ kan Àpótí Majẹmu, ó sì kú níwájú Ọlọrun.