Kronika Keji 34:12-15 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àwọn eniyan náà fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣàkóso wọn ni: Jahati ati Ọbadaya, láti inú ìran Merari, ati Sakaraya ati Meṣulamu, láti inú ìran Kohati. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n mọ̀ nípa ohun èlò orin

13. ni wọ́n ń ṣàkóso àwọn tí wọn ń ru ẹrù, ati àwọn tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi jẹ́ akọ̀wé, àwọn kan wà nídìí ètò ìsìn, àwọn mìíràn sì jẹ́ aṣọ́nà.

14. Nígbà tí wọn ń kó owó tí àwọn eniyan ti mú wá sinu ilé OLUWA jáde, Hilikaya, alufaa rí ìwé òfin OLUWA tí Ọlọrun fún Mose.

15. Hilikaya sọ fún Ṣafani akọ̀wé, ó ní, “Mo rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA.” Ó fún Ṣafani ní ìwé náà,

Kronika Keji 34