1. Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn.
2. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA. Ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀, nípa títẹ̀lé òfin Ọlọrun fínnífínní.
3. Ní ọdún kẹjọ tí Josaya gorí oyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọrun Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Ní ọdún kejila, ó bẹ̀rẹ̀ sí wó àwọn pẹpẹ oriṣa ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati Jerusalẹmu. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera, ó sì fọ́ àwọn ère gbígbẹ́ ati èyí tí wọ́n rọ.