Kronika Keji 3:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹmpili OLUWA ní Jerusalẹmu, níbi ìpakà Onani, ará Jebusi, lórí òkè Moraya, níbi tí OLUWA ti fi ara han Dafidi, baba rẹ̀; Dafidi ti tọ́jú ibẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

2. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà ní ọjọ́ keji oṣù keji ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.

3. Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọrun tí Solomoni fi lélẹ̀ gùn ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9).

Kronika Keji 3