Kronika Keji 28:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ẹ tún wá fẹ́ kó tọkunrin tobinrin Juda ati Jerusalẹmu lẹ́rú. Ṣé ẹ̀yin alára náà kò ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín?

11. Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ dá àwọn arakunrin yín tí ẹ ti kó lẹ́rú pada, nítorí ibinu OLUWA wà lórí yín.”

12. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè kan lára àwọn ará Efuraimu: Asaraya, ọmọ Johanani, Berekaya, ọmọ Meṣilemoti, Jehisikaya, ọmọ Ṣalumu ati Amasa, ọmọ Hadilai dìde, wọ́n tako àwọn tí ń ti ojú ogun bọ̀, wọ́n sọ fún wọn pé,

13. “Ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ìgbèkùn wọnyi wọ ibí wá, kí ẹ tún wá dákún ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹ̀bi tí ó wà lọ́rùn wa tẹ́lẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ tẹ́lẹ̀, ọwọ́ ibinu OLUWA sì ti wà lára Israẹli.”

Kronika Keji 28