Kronika Keji 26:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbogbo àwọn ará Juda fi Usaya, ọmọ ọdún mẹrindinlogun jọba lẹ́yìn ikú Amasaya baba rẹ̀.

2. Ó tún Eloti kọ́, ó gbà á pada fún Juda lẹ́yìn ikú Amasaya, baba rẹ̀.

3. Ọmọ ọdún mẹrindinlogun ni Usaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya, ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀.

4. Ó ṣe nǹkan tí ó tọ́ níwájú OLUWA, bí Amasaya baba rẹ̀.

5. Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.

Kronika Keji 26