Kronika Keji 24:6-9 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nítorí náà, ọba ranṣẹ pe Jehoiada tí ó jẹ́ olórí wọn, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Lefi lọ máa gba owó fún àgọ́ ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn eniyan Juda ati Jerusalẹmu bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pa á láṣẹ?”

7. (Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Atalaya, obinrin burúkú n nì, ti fọ́ ilé Ọlọrun, wọ́n sì ti kó gbogbo ohun èlò mímọ́ ibẹ̀, wọ́n ti lò ó fún oriṣa Baali.)

8. Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àpótí kan tí àwọn eniyan yóo máa sọ owó sí, kí wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.

9. Wọ́n kéde káàkiri Jerusalẹmu ati Juda pé kí wọ́n máa mú owó orí wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ Ọlọrun ti pàṣẹ fún Israẹli ninu aṣálẹ̀.

Kronika Keji 24