1. Jehoṣafati ọba Juda pada ní alaafia sí ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
2. Ṣugbọn Jehu, aríran, ọmọ Hanani lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ṣé ó dára kí o máa ran eniyan burúkú lọ́wọ́, kí o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra OLUWA? Nítorí èyí, ibinu OLUWA ru sí ọ.
3. Sibẹsibẹ àwọn nǹkankan wà tí o ṣe tí ó dára, o run àwọn ère oriṣa Aṣera ní ilẹ̀ yìí, o sì ti ṣe ọkàn rẹ gírí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.”