Kronika Keji 12:3-5 BIBELI MIMỌ (BM)

3. ati ọ̀kẹ́ mẹta (60,000) ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Ijipti. Àwọn ará Libia, àwọn ará Sukiimu, ati àwọn ará Etiopia wà ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

4. Ó gba gbogbo ìlú olódi Juda títí ó fi dé Jerusalẹmu.

5. Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.”

Kronika Keji 12