Kọrinti Kinni 8:11-13 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ìmọ̀ tìrẹ mú ìparun bá ẹni tí ó jẹ́ aláìlera, arakunrin tí Kristi ti ìtorí tirẹ̀ kú.

12. Ẹ̀ ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí àwọn arakunrin yín tí ó jẹ́ aláìlera, ẹ̀ ń dá ọgbẹ́ sí ọkàn wọn, ẹ sì ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi.

13. Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni yóo bá gbé arakunrin mi ṣubú, n kò ní jẹ ẹran mọ́ laelae, kí n má baà ṣe ohun tí yóo gbé arakunrin mi ṣubú.

Kọrinti Kinni 8