Kọrinti Keji 6:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán.

2. Nítorí Ọlọrun sọ pé,“Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé;mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.”Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà.

Kọrinti Keji 6