5. ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu.
6. A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa.
7. Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́.
8. Nítorí ojú kò tì mí bí mo bá ń ṣe ìgbéraga ní àṣejù nípa àṣẹ tí a ní, tí Oluwa fi fún mi, láti lè mu yín dàgbà ni, kì í ṣe láti fi bì yín ṣubú.
9. N kò fẹ́ kí ẹ rò pé mò ń fi àwọn ìwé tí mò ń kọ dẹ́rù bà yín.