1. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani tán, OLUWA wí fún Joṣua pé,
2. “Yan ọkunrin mejila láàrin àwọn eniyan náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
3. Kí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n gbé òkúta mejila láàrin odò Jọdani yìí, lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa dúró sí, kí wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ bí ẹ ti ń lọ, kí ẹ sì kó wọn jọ sí ibi tí ẹ óo sùn lálẹ́ òní.”
4. Joṣua bá pe àwọn ọkunrin mejila tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan;
5. ó wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, sí ààrin odò Jọdani, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan sì gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká rẹ̀. Kí iye òkúta tí ẹ óo gbé jẹ́ iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli.