Joṣua 19:33-38 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Ààlà ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní Helefi, láti ibi igi oaku tí ó wà ní Saananimu, Adaminekebu, ati Jabineeli, títí dé Lakumu, ó sì pin sí odò Jọdani.

34. Níbẹ̀ ni ààlà náà ti yipada lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn sí Asinotu Tabori. Láti ibẹ̀, ó lọ títí dé Hukoku, ó lọ kan ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni ní apá ìhà gúsù, ó sì kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri lápá ìwọ̀ oòrùn, ati ti Juda ní apá ìlà oòrùn létí odò Jọdani.

35. Àwọn ìlú olódi tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni Sidimu, Seri, Hamati, Rakati, Kinereti;

36. Adama, Rama, Hasori;

37. Kedeṣi, Edirei, Enhasoru,

38. Yironi, Migidalieli, Horemu, Betanati ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo ìlú ati àwọn ìletò wọn jẹ́ mọkandinlogun.

Joṣua 19