Joṣua 18:11-13 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn wà ní ààrin ilẹ̀ ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Josẹfu.

12. Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni.

13. Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni.

Joṣua 18