20. Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà.
21. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”
22. Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu.
23. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo.