6. Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.
7. Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi.
8. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.
9. Ẹnikẹ́ni tí kò bá máa gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi, ṣugbọn tí ó bá tayọ rẹ̀, kò mọ Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi mọ Baba ati Ọmọ.