Jobu 14:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́?N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi,n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé.

15. O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn,o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16. Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi,o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi.

17. O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò,o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀.

18. “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú,a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀.

19. Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta,tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ,bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo.

20. O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ,o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ.

21. Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀,a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i.

22. Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀,ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”

Jobu 14