Jobu 10:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí,ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?

10. Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà,tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?

11. Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí,tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀.

12. O fún mi ní ìyè,o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró.

13. Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ,mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé,

14. bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi,o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà.

15. Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé,ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn,nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀.

Jobu 10