1. “Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu.
2. Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀.
3. Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”