15. Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́.
16. Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko.
17. Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni.
18. Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.