14. Gbogbo àwọn olólùfẹ́ yín ti gbàgbé yín;wọn kò bìkítà nípa yín mọ́,nítorí mo ti nà yín bí ọ̀tá mi,mo sì fi ìyà jẹ yín bí ọ̀tá tí kò láàánú,nítorí àṣìṣe yín pọ̀,nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà.
15. Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún,nítorí ìnira yín tí kò lóògùn?Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlàni mo ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi dé ba yín.
16. Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run.Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn.Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó.N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù.
17. N óo fun yín ní ìlera,n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù,Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ”