4. Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí.
5. Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn.
6. Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀, tí a kò ní pe ibí yìí ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́. Àfonífojì ìpànìyàn ni a óo máa pè é.
7. N óo sọ ìmọ̀ àwọn ará Juda ati ti àwọn ará ìlú Jerusalẹmu di òfo, n óo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn fi idà pa wọ́n. N óo sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.
8. N óo sì sọ ìlú yìí di ohun ẹ̀rù ati àrípòṣé, ẹ̀rù ìlú náà yóo sì máa ba gbogbo ẹni tí ó bá kọjá níbẹ̀, wọn yóo máa pòṣé nítorí àjálù tí ó dé bá a.