1. OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ ra aṣọ funfun kan, kí o lọ́ ọ mọ́ ìdí, má sì tì í bọ omi rárá.”
2. Mo bá ra aṣọ funfun náà, bí OLUWA ti wí, mo lọ́ ọ mọ́ ìdí.
3. OLUWA tún sọ fún mi lẹẹkeji pé,
4. “Dìde, mú aṣọ funfun tí o rà, tí o lọ́ mọ́ ìdí, lọ sí odò Yufurate, kí o lọ fi pamọ́ sí ihò àpáta níbẹ̀.”
5. Mo bá lọ fi pamọ́ sí ẹ̀bá odò Yufurate bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi.
6. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, OLUWA sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí odò Yufurate kí o mú aṣọ tí mo ní kí o fi pamọ́ sibẹ wá.”
7. Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́.
8. OLUWA sọ fún mi pé,
9. “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo ṣe sọ ògo Juda ati ti Jerusalẹmu di ìbàjẹ́.
10. Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun.