Jẹnẹsisi 40:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tí Josẹfu rí wọn, ó rí i pé ọkàn wọn dàrú.

7. Ó bá bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì lónìí?”

8. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lá àlá kan ni, a kò sì rí ẹni bá wa túmọ̀ rẹ̀.”Josẹfu dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣebí Ọlọrun ni ó ni ìtumọ̀ àlá? Ẹ rọ́ àlá náà fún mi.”

9. Agbọ́tí bá rọ́ àlá tirẹ̀ fún Josẹfu, ó ní, “Mo rí ìtàkùn àjàrà kan lójú àlá.

10. Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n.

Jẹnẹsisi 40