30. Bí Isaaki ti súre fún Jakọbu tán, Jakọbu fẹ́rẹ̀ má tíì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi ti oko ọdẹ dé.
31. Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.”
32. Isaaki, baba rẹ̀ bi í pé, “Ìwọ ta ni?” Esau bá dá a lóhùn pé, “Èmi ọmọ rẹ ni. Èmi, Esau, àkọ́bí rẹ.”
33. Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.”
34. Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.”
35. Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.”