Jẹnẹsisi 23:19-20 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Lẹ́yìn náà, Abrahamu lọ sin òkú Sara sinu ihò ilẹ̀ Makipela, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, ní agbègbè Heburoni ní ilẹ̀ Kenaani.

20. Ilẹ̀ náà ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu láti máa lò bí itẹ́ òkú.

Jẹnẹsisi 23