19. Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀.
20. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sọ fún Abrahamu pé Milika ti bímọ fún Nahori arakunrin rẹ̀.
21. Usi ni àkọ́bí, Busi ni wọ́n bí tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà Kemueli tíí ṣe baba Aramu.
22. Lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Kesedi, Haso, Pilidaṣi, Jidilafi ati Betueli.