Jẹnẹsisi 14:4-6 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Fún ọdún mejila gbáko ni àwọn ọba maraarun yìí fi sin Kedorilaomeri, ṣugbọn ní ọdún kẹtala, wọ́n dìtẹ̀.

5. Ní ọdún kẹrinla, Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀ wá, wọ́n ṣẹgun Refaimu tí ó wà ní Aṣiterotu Kanaimu. Bákan náà, wọ́n ṣẹgun àwọn Susimu tí wọ́n wà ní Hamu, àwọn Emimu tí wọ́n wà ní Ṣafe-kiriataimu,

6. ati àwọn ará Hori ní orí Òkè Seiri, títí dé Eliparani, lẹ́bàá aṣálẹ̀.

Jẹnẹsisi 14