14. Nígbà tí Abramu gbọ́ pé wọ́n ti mú ìbátan òun lẹ́rú, ó kó ọọdunrun ó lé mejidinlogun (318) ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, tí ó sì ti kọ́ ní ogun jíjà, ó lépa àwọn tí wọ́n mú Lọti lẹ́rú lọ títí dé ilẹ̀ Dani.
15. Ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ní òru ọjọ́ náà. Òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ yí àwọn ọ̀tá náà po, wọ́n ṣí wọn nídìí, wọ́n sì lépa wọn títí dé ìlú Hoba ní apá ìhà àríwá Damasku.
16. Abramu gba gbogbo ìkógun tí wọ́n kó pada, ó gba Lọti, ìbátan rẹ̀ pẹlu ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, ati àwọn obinrin ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan mìíràn.
17. Nígbà tí Abramu ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n jọ pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Sodomu jáde lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (tí ó tún ń jẹ́, àfonífojì ọba).