4. Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣai, Taṣiṣi, Kitimu ati Dodanimu.
5. Àwọn ni baba ńlá àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ati àwọn erékùṣù, tí wọ́n tàn káàkiri. Àwọn ọmọ Jafẹti nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
6. Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani.
7. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba ati Dedani.
8. Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé.