7. Nítorí náà, ẹ wò ó! Mo ti nawọ́ ìyà si yín, n óo sì fi yín ṣe ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. N óo pa yín run láàrin àwọn eniyan ilẹ̀ ayé, n óo sì pa yín rẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
8. OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Moabu ń wí pé ilẹ̀ Juda dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
9. nítorí náà, n óo tú àwọn ìlú Moabu tí wọ́n wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì ká: àwọn ìlú tí ó dára jù ní ilẹ̀ Moabu, Beti Jẹṣimoti, Baali Meoni ati Kiriataimu ká.
10. N óo fún àwọn ará ìlà oòrùn ní òun ati ilẹ̀ Amoni, wọn óo di ìkógun, kí á má baà ranti rẹ̀ mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
11. N óo ṣe ìdájọ́ àwọn ará Moabu; wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA!”
12. OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí àwọn ará Edomu gbẹ̀san lára àwọn ará Juda, wọ́n sì ṣẹ̀ nítorí ẹ̀san tí wọ́n gbà.