Isikiẹli 25:13-16 BIBELI MIMỌ (BM)

13. N óo nawọ́ ìyà sí Edomu, n óo pa ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀ run. N óo sọ ọ́ di ahoro láti Temani títí dé Dedani. Ogun ni yóo pa wọ́n.

14. Àwọn eniyan mi, Israẹli, ni n óo lò láti gbẹ̀san lára Edomu. Bí inú ti bí mi tó, ati bí inú mi ṣe ń ru tó, ni wọn yóo ṣe fi ìyà jẹ Edomu. Wọn óo wá mọ̀ bí mo ti lè gbẹ̀san tó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA Ọlọrun ní, “Àwọn ará Filistia gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn, wọn sì fi ìkórìíra àtayébáyé pa wọ́n run,

16. nítorí náà, n óo nawọ́ ìyà sí wọn, n óo pa àwọn ọmọ Kereti run, n óo pa àwọn tí ó kù sí etí òkun rẹ́.

Isikiẹli 25