Isikiẹli 20:28-35 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀.

29. Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní.

30. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn?

31. Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi.

32. Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta.

33. “Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín.

34. N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu.

35. N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju.

Isikiẹli 20