13. N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí.
14. Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.
15. “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé.
16. N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”