2. Lọ́jọ́ karun-un oṣù náà, tíí ṣe ọdún karun-un tí wọ́n ti mú ọba Jehoiakini lọ sí ìgbèkùn,
3. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára.
4. Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà.
5. Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan.
6. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin.