1. Àwọn kan wá láti Judia tí wọn ń kọ́ àwọn onigbagbọ pé, “Bí ẹ kò bá kọlà gẹ́gẹ́ bí àṣà ati Òfin Mose, a kò lè gbà yín là!”
2. Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.